14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́miìwọ kì yóò sì dárí àìṣedédé mi jìn.
15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.Nítorí mo wà nínú ìtọ́jú púpọ̀, mo sì wo ìpọ́jú mi.
16 Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìhún;àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
17 Ìwọ sì tún sọ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ sí midi ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrúnú rẹ di púpọ̀ sí mi;Àyípadà àti ogun dó tì mí.
18 “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?Áà! èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi
19 Tí ó bá lejẹ́ pé èmi le wà láàyè,À bá ti gbé mi láti inú lọ isà-òkú.
20 Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárádáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ minítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan