3 Àlùfáà náà ni ó gbọdọ̀ yẹ egbò ara rẹ̀ wò: bí irun egbò náà bá di funfun tí egbò náà sì dà bí i pé ó jinlẹ̀ kọjá awọ ara: èyí jẹ́ àrùn ara tí ó le è ràn: Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò kí ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé aláìmọ́ ni ẹni náà.
4 Bí àpá ara rẹ̀ bá funfun tí ó sì dàbí ẹni pé kò jinlẹ̀ jù awọ ara, tí irun rẹ̀ kò sì yípadà sí funfun kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.
5 Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà ṣíbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.
6 Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́
7 Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà.
8 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fi hàn pé kò mọ́. Àrùn ara tí ń ràn ni èyí.
9 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà.