5 Ẹ pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ṣe ìgbọ́ràn sí wọn yóò máa gbé nípa wọn, Èmi ni Olúwa.
6 “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.
7 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.
8 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni.
9 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.
10 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòòhò wọn, ìhòòhò ìwọ fúnrarẹ ni.
11 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya bàbá rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún bàbá rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni