Onídájọ́ 8:25-31 BMY

25 Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀.

26 Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

27 Gídíónì fi àwọn wúrà náà ṣe Éfódì èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Òfírà ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ ara wọn di aṣẹ́wó nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ fún Gídíónì àti ìdílé rẹ̀.

28 Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Mídíánì ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbérí mọ́. Ní ọjọ́ Gídíónì, Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.

29 Jerub-Báálì ọmọ Jóásìa padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.

30 Àádọ́rin ọmọ ni ó bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.

31 Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣékémù, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ábímélékì.