1 Olúwa kórìíra òṣùwọ̀n èkéṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
2 Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì déṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
3 Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn.
4 Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínúṣùgbọ́n òdodo a máa gba ni lọ́wọ́ ikú.
5 Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọnṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fàá lulẹ̀.
6 Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n làṣùgbọ́n ìdẹkùn ètè búburú mú aláìsòótọ́.
7 Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parungbogbo ohun tó ń fojú sọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já sófo.