12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
13 Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́.
14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubúṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
15 Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.
16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.