1 Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọ̀tí líleẹnikẹ́ni tí ó bá sìnà nìpaṣẹ̀ wọn kò gbọ́n.
2 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún;ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
3 Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjàṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹnítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.