1 Nígbà tí Olúwa mú ìkòlọ Síónì padà,àwa dàbí ẹni tí o ń lá àlá.
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,àti ahọ́n wa kọ orin;nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn aláìkọlà pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,bí ìṣàn omi ní gúsù.