1 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,ọmọ aládé ni ìwọ fi òdodo Rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdàjọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú òdodoyóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn talákà Rẹ
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyànàti òkè kékèké nípa òdodo
4 Yóò dábò bò àwọn tí a pọ́n lójú láàrin àwọn ènìyànyóò gba àwọn ọmọ aláìní;yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòsì àti aláìníyóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,yóò ti pẹ́ tó,láti ìran díran.
6 Yóò dàbí òjò tí o ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ Rẹ̀ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;títí tí oṣùpá kò fi ní sí mọ́