11 Tírẹ̀ ni ògo àti agbára títí láé (Àmín)
12 Nítorí Sílà, arákùnrin wa olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkurú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.
13 Ìjọ tí ń bẹ ní Bábílónì, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Máàkù ọmọ mi pẹ̀lú.
14 Ẹ fi ìfẹ́nukònú ìfẹ́ kí ara, yín (Àmín)