2 Jòhánù 1 BMY

1 Alàgbà,Sì àyànfẹ́ obìnrin-ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmí nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;

2 nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

3 Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlààáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

4 Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pá àṣẹ fún wa.

5 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtèkèkọ́ṣe, pé kí àwá fẹ́ràn ara wa.

6 Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

7 Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jésù Kírísítì wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ̀tàn àti Aṣòdì sí Kírísítì.

8 Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.

9 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kírísítì, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.

10 Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú àbọ̀.

11 Nítorí ẹni tí ó bá kí i kú àbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

12 Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.

orí

1