14 Gẹ́gẹ́ bí ẹyín pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apákan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jésù Olúwa.
15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnun láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jànfààní ìgbà méjì.
16 Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìn àjò mi sí Makedóníà àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedóníà àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìn àjò mi sí Jùdíà.
17 Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbérò bẹ́ẹ̀, èmi há ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?
18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ati bẹ́ẹ̀ kọ́.
19 Nítorí pé Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàárin yín nípaṣẹ̀ èmí àti Silífánù àti Tímótíù, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.
20 Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kírísítì. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípaṣẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.