2 Tẹsalóníkà 3 BMY

Ìtọrọ Àdúrà

1 Ní àkótan, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín.

2 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́.

3 Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.

4 Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pa láṣẹ fún-un yín ni ẹ̀yin ń ṣe.

5 Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín sọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kírísítì.

Ìkìlọ̀ Ní Ṣíṣe Ìmẹ́lẹ́

6 Ní orúkọ Jésù Kirisítì Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún-un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.

7 Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa farawé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.

8 Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣisẹ́ tọ̀sán-tòru kí a má baà di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.

9 Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti bèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.

10 Nítorí nígbà tí àwà wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún-un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

11 A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrin yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlé-kiri.

12 Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ́ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jésù Kírísítì Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.

13 Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere síṣe.

14 Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa ofin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ ṣààmí sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í.

15 Ṣíbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀ta, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún-un gẹ́gẹ́ bí arakùnrin yín.

Ìkínì Ìkẹ́yín

16 Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

17 Èmi Pọ́ọ̀lù fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.

18 Kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.

orí

1 2 3