Ìfihàn 7:8-14 BMY

8 Láti inú ẹ̀yà Sebulúnì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.

9 Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn.

10 Wọn sì kígbe ni ohùnrara, wí pé:“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wátí o jókòó lórí ìtẹ́,àti ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn!”

11 Gbogbo àwọn ańgẹ́lì sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run.

12 Wí pe:“Àmín!Ìbùkún, àti ògo,àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!Àmín!”

13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

14 Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.