22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe títí àwọn méjèèje fi kú láìbímọ. Ní òpin gbogbo rẹ̀, obìnrin tí a ń wí yìí náà kú.
23 Ohun tí a fẹ́ mọ̀ nìyì: Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn arákùnrin méjèèje ló fẹ́ obìnrin náà, ìyàwó o ta ni yóò jẹ́ nínú wọn lọ́jọ́ àjíǹde?”
24 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ìṣòro yín ni wí pé, ẹ kò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti agbára Ọlọ́run.
25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn ańgẹ́lì.
26 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Ẹ́kísódù, nípa Mósè àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mósè pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’
27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
28 Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jésù ti dáhùn dáadáa. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”