10 Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
11 Àti pẹ̀lú,“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà;ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
12 Àìṣáyà sì tún wí pé,“Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá,òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà;Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”
13 Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
14 Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.
15 Mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fifún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
16 láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.