6 kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
7 Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run.
8 Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀,
9 kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà,Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
11 Àti pẹ̀lú,“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà;ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
12 Àìṣáyà sì tún wí pé,“Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá,òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà;Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”