8 Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀,
9 kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà,Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
11 Àti pẹ̀lú,“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà;ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
12 Àìṣáyà sì tún wí pé,“Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá,òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà;Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”
13 Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
14 Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.