Àwọn Ọba Keji 22:14-20 BM

14 Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà.

15 Ó bá rán wọn pada, ó ní: “Ẹ lọ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé,

16 ‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà.

17 Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń sun turari sí àwọn oriṣa láti mú mi bínú nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Nítorí náà, inú mi yóo ru sí ibí yìí, kò sì ní rọlẹ̀.

18 Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada,

19 ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi.

20 Nítorí náà, n kò ní fi ìyà jẹ Jerusalẹmu nígbà tí ó wà láàyè, n óo jẹ́ kí ó kú ní alaafia.” ’ ”Àwọn ọkunrin náà sì lọ jíṣẹ́ fún Josaya ọba.