10 Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.
11 Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
13 Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.
14 Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.
15 Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.
16 Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.