13 Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.
14 Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.
15 Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.
16 Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.
17 Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀,ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù.
18 Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.
19 Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.