5 Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́,ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.
6 Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.
7 Yẹra fún òmùgọ̀,nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.
8 Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́nni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.
9 Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.
10 Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.
11 Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.