7 Yẹra fún òmùgọ̀,nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.
8 Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́nni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.
9 Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.
10 Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.
11 Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
13 Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.