1 Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì,
2 tí o bá bọ́ sinu tàkútétí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,
3 o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ.Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi,kí o lè gba ara rẹ là:lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.
4 Má sùn,má sì tòògbé,
5 gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ,àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
6 Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ,ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.