34 OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda.
35 Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn,
36 n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé.
37 N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán.
38 N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn.
39 Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”