1 Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun,tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀!
2 Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan,kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo!
3 Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjàpẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà.Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀,òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti;òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye,àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkúbí wọn tí ń lọ!
4 Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe,tí wọ́n fanimọ́ra,ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró,ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a;nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ,ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.