13 Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu.
14 Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
15 Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ.
16 Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni.
17 Ó bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ bí ẹ ti ń rìn bọ̀? Kí ló dé tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀?”
18 Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?”
19 Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan.