14 Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú:
15 O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada.
16 Yio si ma ṣe àmi li ọwọ́ rẹ, ati ọjá-igbaju lagbedemeji oju rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni Egipti.
17 O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti.
18 Ṣugbọn Ọlọrun mu wọn yi lọ li ọ̀na ijù Okun Pupa: awọn ọmọ Israeli jade lọ kuro ni ilẹ Egipti ni ihamọra.
19 Mose si gbé egungun Josefu lọ pẹlu rẹ̀; nitori ibura lile li o mu awọn ọmọ Israeli bu pe, Lõtọ li Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò; ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lọ pẹlu nyin kuro nihin.
20 Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù.