1 OLUWA si wi fun Mose pe,
2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o dari, ki nwọn ki o si dó si iwaju Pi-hahirotu, li agbedemeji Migdolu on okun, niwaju Baal-sefoni: lọkankan rẹ̀ li ẹba okun ni ki ẹnyin ki o dó si.
3 Nitoriti Farao yio wi niti awọn ọmọ Israeli pe, Nwọn há ni ilẹ na, ijù na sé wọn mọ́.
4 Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃.
5 A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa?