11 Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá,
12 Pẹlupẹlu Abiṣai ọmọ Seruiah pa ẹgbãsan ninu awọn ara Edomu li afonifoji Iyọ̀.
13 O si fi ẹgbẹ-ogun si Edomu: ati gbogbo awọn ara Edomu si di iranṣẹ Dafidi. Bayi li Oluwa ngbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
14 Bẹ̃ ni Dafidi jọba lori gbogbo Israeli, o si ṣe idajọ ati otitọ larin awọn enia rẹ̀.
15 Joabu ọmọ Seruiah si wà lori ogun; ati Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọwe-iranti.
16 Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Abimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; ati Ṣafṣa ni akọwe;
17 Benaiah ọmọ Jehoiada li o si wà lori awọn Kereti ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si li olori lọdọ ọba.