1 O SI ṣe lẹhin eyi, ni Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni kú, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
2 Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.
3 Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na?
4 Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ.
5 Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá.