9 Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá?
10 Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati.
11 Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀.
12 A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀.
13 O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ.
14 Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.
15 Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.