6 Idà Oluwa kun fun ẹ̀jẹ, a mu u sanra fun ọ̀ra, ati fun ẹ̀jẹ ọdọ-agutan ati ewurẹ, fun ọrá erẽ àgbo: nitoriti Oluwa ni irubọ kan ni Bosra, ati ipakupa nla kan ni ilẹ Idumea.
7 Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra.
8 Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni.
9 Odò rẹ̀ li a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi-õrun, ilẹ rẹ̀ yio si di ọ̀dà ti njona.
10 A kì o pa a li oru tabi li ọsan; ẹ̃fin rẹ̀ yio goke lailai: yio dahoro lati iran de iran; kò si ẹnikan ti yio là a kọja lai ati lailai.
11 Ṣugbọn ẹiyẹ ofú ati àkala ni yio ni i; ati owiwi ati iwò ni yio ma gbe inu rẹ̀: on o si nà okùn iparun sori rẹ̀, ati okuta ofo.
12 Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan kì yio si nibẹ ti nwọn o pè wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yio si di asan.