1 O si di igbati o ṣe li ọdun ikẹrinla Hesekiah ọba, Sennakeribu ọba Assiria wá dótì gbogbo ilu olodi Juda, o si kó wọn.
2 Ọba Assiria si rán Rabṣake lati Lakiṣi lọ si Jerusalemu, ti on ti ogun nla, sọdọ Hesekiah ọba. O si duro lẹba idari omi abàta oke, li opopo pápa afọṣọ.
3 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkia, olùtọ́ju ile, jade tọ̀ ọ wá, pẹlu Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu, akọwe iranti.
4 Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ wi fun Hesekiah nisisiyi, pe, Bayi li ọba nla, ọba Assiria wi, pe, Igbẹkẹle wo ni eyi ti iwọ gbe ara le yi?
5 Iwọ wi pe, Mo ni, (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn) emi ni ìmọ ati agbara fun ogun jija: njẹ tani iwọ tilẹ gbẹkẹle ti iwọ fi nṣọ̀tẹ si mi?
6 Wò o, iwọ gbẹkẹle ọpá iyè fifọ́ yi, le Egipti; eyiti bi ẹnikẹni ba fi ara tì, yio wọnu ọwọ́ rẹ̀, yio si gún u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri si gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.