14 Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn.
15 Kini olufẹ mi ni iṣe ni ile mi? nigbati nwọn nṣe buburu pupọ bayi? adura on ẹran mimọ́ ha le mu ibi kọja kuro lọdọ rẹ? bi o ba ri bayi? nigbana jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
16 Oluwa pè orukọ rẹ ni igi Olifi tutu, didara, eleso rere: ṣugbọn nisisiyi o fi ariwo irọkẹkẹ nla dá iná lara rẹ̀, ẹka rẹ̀ li o si faya.
17 Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.
18 Oluwa si ti mu mi mọ̀, emi si mọ̀: nigbana ni iwọ fi iṣe wọn hàn mi.
19 Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.
20 Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ.