5 Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi.
6 Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn.
7 Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju.
8 Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi.
9 Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u.
10 Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran.
11 Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi.