3 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA.
4 Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u.
5 Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
6 Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u.
7 Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na:
8 Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ:
9 Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.