1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi.
2 Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀.
3 Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀.
4 O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ.
5 Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6 Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.
7 Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e.