7 Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́.
8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
9 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si pe gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli jọ pọ̀:
10 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi.
11 Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA.
12 Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi.
13 Ki iwọ ki o si mu awọn ọmọ Lefi duro niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì fun OLUWA.