6 Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi.
7 Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada.
8 Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri.
9 Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa.
10 Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia.
11 Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe.
12 Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn.