21 Nitori Ọlọrun yio fọ ori awọn ọta rẹ̀, ati agbari onirun ti iru ẹniti nrìn sibẹ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
22 Oluwa wipe, emi o tun mu pada lati Baṣani wá, emi o tun mu wọn pada lati ibu okun wá.
23 Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na.
24 Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì.
25 Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu.
26 Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá.
27 Nibẹ ni Benjamini kekere wà, pẹlu olori wọn, awọn ọmọ-alade Juda pẹlu awọn igbimọ wọn, awọn ọmọ-alade Sebuloni, ati awọn ọmọ-alade Naftali.