9 Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju.
10 Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ.
11 Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.
12 Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju.
13 Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú.
14 Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ.
15 Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́.