13 Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori;
14 Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere.
15 Bẹ̃ sá ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere iṣe, ki ẹ le dá òpe awọn wère enia lẹkun:
16 Bi omnira, laisi lo omnira nyin fun ohun bibo arakàn nyin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹrú Ọlọrun.
17 Ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia. Ẹ fẹ awọn ará. Ẹ bẹru Ọlọrun. Ẹ bọ̀wọ fun ọba.
18 Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu.
19 Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun.