14 Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin.
15 Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun.
16 Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́.
17 Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.
18 Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.