35 Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta.
36 O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ.
37 Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi.
38 Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀.
39 Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a.
40 Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni?
41 Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò.