11 Mo si wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ìha íwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun.
12 Ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ-ọba li a o sọ sinu òkunkun lode, nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà.
13 Jesu si wi fun balogun ọrún na pe, Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ́, bẹ̃ni ki o ri fun ọ. A si mu ọmọ-ọdọ rẹ̀ larada ni wakati kanna.
14 Nigbati Jesu si wọ̀ ile Peteru lọ, o ri iya aya rẹ̀ dubulẹ àisan ibà.
15 O si fi ọwọ́ bà a li ọwọ́, ibà si fi i silẹ; on si dide, o si nṣe iranṣẹ fun wọn.
16 Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada:
17 Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.