4 Jesu si wi fun u pe, Wò o, máṣe sọ fun ẹnikan; ṣugbọn mã ba ọ̀na rẹ lọ, fi ara rẹ hàn fun awọn alufa, ki o si fi ẹ̀bun ti Mose palaṣẹ li ẹrí fun wọn.
5 Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ,
6 O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀.
7 Jesu si wi fun u pe, emi mbọ̀ wá mu u larada.
8 Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.
9 Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e.
10 Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli.