11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;yóò wó ibi gíga yín palẹ̀a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjìkúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kanbẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,tí ń gbé Samáríà kúròní igun ibùsùn wọnní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run alágbára.
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run;ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúròyóò sì wó lulẹ̀.”
15 “Èmi yóò wó ilé òtútùlulẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀ẹ̀rùn;ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbéa ó sì pa ilé ńlá náà run,”ni Olúwa wí.