8 Kìnnìún ti bú ramúramùta ni kì yóò bẹ̀rù? Olúwa Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ta ni le ṣe àìsọtẹ́lẹ̀?
9 Ẹ kéde ní ààfin Áṣídódùàti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì.“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samáríà;Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrin rẹ̀àti ìnílára láàrin àwọn ènìyàn rẹ.”
10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,“Ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;yóò wó ibi gíga yín palẹ̀a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjìkúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kanbẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,tí ń gbé Samáríà kúròní igun ibùsùn wọnní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run alágbára.
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run;ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúròyóò sì wó lulẹ̀.”