1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Báṣánì lórí òkè Samáríà,ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni talákà lára,tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”
2 Olúwa Ọlọ́run ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra:“Àkókò náà yóò dé nítòótọ́nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ,ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.
3 Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọgba àárin odi yíyaa ó sì lé e yín sí Hámónà,”ni Olúwa wí.
4 “Ẹ lọ sí Bétélì láti dẹ́ṣẹ̀;ẹ lọ sí Gílígálì kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i.Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá,ìdámẹ́wàá yín ní ọdọdún mẹ́ta.